LYRIC

Yes ke. Ah ah, O ya to, Odika serious,

Jesu ni ng ma sin titi aye mi (Jesu Kristi Omo Olorun Iwo ni ng ma sin).
Jesu ni ng ma sin titi aye mi (One more time please, double up please)
Jesu ni ng ma sin titi aye (oh yes)
Jesu ni ng ma sin titi aye mi

Ta leyin ma sin o, ta leyin ma sin, ta leyin ma sin
Ta ni iwo ma sin, ta lo fe ma sin, Jesu le mi ma sin
Eni to f’ara Re rubo lati ra mi pada, oun le mi ma sin
Ona tororo, to lo s’ona iye, ohun le mi ma to
Akoda aye, aseda orun baba, iwo le mi ma sin o titi aye mi

Jesu ni ng ma sin titi aye mi Mo gba Olorun Baba Eledure gbo
Jesu ni ng ma sin titi aye mi At’ omo Re nikan soso, Jesu Kristi Oluwa wa
Jesu ni ng ma sin titi aye Mo gba Emi Mimo gbo, Ijo mimo enia Olorun
Jesu ni ng ma sin titi aye mi Ajinde iye ayeraye

Eni to ba leti ko gbo, ohun ti Emi ng so fun ‘jo
Eni to ba segun, ohun ni yoo je manna
Eni to leti ko gbo o, ikilo t’Oluwa se
Ma se sin Olorun miran, Olorun owu ni Baba
Aye dori kodo, O s’orisun nu
Ko sin Olorun mo, ife tara ni won ng se
Ta ni eyin ma sin laye, ta le fe ma sin o, e gbe si mi l’eti

Jesu ni ng ma sin titi aye mi B’aye fe b’aye ko , Jesu ni ma ba lo
Jesu ni ng ma sin titi aye mi Ohun loko opo, Baba alaini Baba
Jesu ni ng ma sin titi aye O gbe ‘nu wundia s’ola, ogbe ‘nu adelebo sewa
Jesu ni ng ma sin titi aye mi Olopo ajobo wa, Oba awon Oba
Jesu ni ng ma sin titi aye mi

Ranti Olorun nigba ewe, (k’aye re ko le da)
Jesu, Emmanueli Christi – (ti Nazareti)
Ohun le mi ma sin – (titi aye mi)
Ta leyin ma sin – (Jesu ni)
Jesu le ma sin – (lai s’iye meji)
Ta leyin ma sin laye – (Jesu ni)
Bo se mi ati dile mi – (Oluwa lawa o ma sin)
Ta l’olugbala re – (Jesu ni)
Ki loruko Re o – (Jesu ni)
Araba ribi raba ribi raba ribi (Jesu ni)
Araba ribi raba ribi rabata (Jesu ni)
Oyigi yigi yigi yigi yigi (Jesu ni)
Ki l’oruko Re o (Jesu ni)
Ki l’oruko Re se (Jesu ni)
Omo Olorun tooto (Jesu ni)
E ba mi poruko Re o (Jesu ni)
Gbongbo idile Jesse (Jesu ni)
Akobi ninu orun (Jesu ni)
Ta l’eyin ma sin o (Jesu ni)
Jesu l’emi ma sin o (Jesu ni)
Oya jewo igbagbo re (Jesu ni)
Ore mi jewo igbagbo re (Jesu ni)

Jesu ni ng ma sin titi aye mi Arewa ti okan mi fe, iyebiye ni fun mi
Jesu ni ng ma sin titi aye mi Ohun ni itanna ipado, imole ninu okunkun
Jesu ni ng ma sin titi aye Mo m’ore ti mo ni, Afeni fere ni
Jesu ni ng ma sin titi aye mi A so re ma siregun, Agba ni l’agbatan
Jesu ni ng ma sin titi aye mi

Bi gbogbo aye ko E o, mi o le ko E Baba
Mamoni, kii se fun mi lati sin
Ohun aye a ra m’aye, asan lori asan
Vanity upon vanity (vanity)
Ohun aye a baye lo (orun ni sura miwa)

Ranti eleda re, N’igba ewe, t’ojo ibi koi de
Ranti Eleda re, Nigba idera, Tohun gbogbo dara
Ranti igba isaju, Emi l’Olorun, Ko s’eni bi Re
Ranti bi iwo ti gba a, Ati bo se gbo, Ko ma jebi ejo
Ranti Olorun, Nigba gbogbo, Pa ofin Re mo

Yin baba yin Baba, fijo ayo yin Baba (Yin baba yin Baba, fijo ayo yin Baba)
Yin Jesu o o o , fijo ayo yin in (Yin baba yin Baba, fijo ayo yin Baba)
Kawo e so ke yin Baba, Bere mole fijo be (Yin baba yin Baba, fijo ayo yin Baba)
Fo s’oke yin Baba, f’atewo yin baba (Yin baba yin Baba, fijo ayo yin Baba)
F’inu mimo yin baba, f’emi otito yin baba (Yin baba yin Baba, fijo ayo yin Baba)
Filu lilu yin baba, forin kiko yin baba (Yin baba yin Baba, fijo ayo yin Baba)
Bere mole yin baba, kawo e soke yin baba (Yin baba yin Baba, fijo ayo yin Baba)
Fiyin f’olu ara mi, Fiyin folu orun (Yin baba yin Baba, fijo ayo yin Baba)
Yin Jesu o o, titi aye (Yin baba yin Baba, fijo ayo yin Baba)

 


Added by

admin

SHARE

ADVERTISEMENT

VIDEO